Posts

Showing posts from December, 2020

Wọn gun ẹni kan pa nibi ija awọn eegun atawọn Ibo l’Akurẹ

Image
ÌRÒYÌN Wọn gun ẹni kan pa nibi ija awọn eegun atawọn Ibo l’Akurẹ   Sola Lawson, Akurẹ Ẹni kan ni wọn lo ti pade iku ojiji lasiko tawọn ọmọ ẹyin egungun kan atawọn ọmọ Ibo to n taja lagbegbe Ọjaa’ba, niluu Akurẹ, kọju ija sira wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii. Ẹnikan tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ sọ fun wa pe awọn oniṣowo ọhun ni wọn kọkọ gun ọkan lara awọn ọmọlẹyin egungun naa lọbẹ pa laduugbo Odopetu. Eyi lo bi awọn ẹgbẹ rẹ ninu ti wọn fi lọọ ya bo ibi tawọn ọmọ Ibo ti n taja niwaju ileetaja Olukayọde, eyi to wa nitosi Ọjaa’ba lati gbẹsan iku ọkan ninu wọn. Awọn janduku ọhun ni wọn n yinbọn kikan kikan, ti gbogbo eto ọrọ aje ọja agbegbe naa si dorikodo pẹlu bi olukuluku awọn ontaja ṣe fi ọja wọn silẹ, ti won si n sa asala fun ẹmi wọn. O to bii wakati kan ti wọn fi wa lẹnu rẹ kawọn ọlọpaa too waa tu wọn ka

Wọn ji ọlọpaa gbe ni Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, wọn tun ba mọto wọn jẹ

Image
ÌRÒYÌN Wọn ji ọlọpaa gbe ni Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, wọn tun ba mọto wọn jẹ   Sola Lawson Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n wa ọlọpaa kan, Emmanuel Gene, ti awọn janduku kan ji gbe niluu Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, ipinlẹ Ogun. Ṣaaju asiko yii ni baalẹ ilu naa ti kọwe ẹsun si ileeṣẹ ọlọpaa pe awọn kan ninu ilu naa ni awọn nnkan ija oloro lọwọ, eyi ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi lagbegbe naa. ALAROYE gbọ pe ọlọpaa mẹẹẹdogun atawọn ẹṣọ fijilante bii marundinlogoji lawọn ọlọpaa ko lọ sinu ilu naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii. Ọkan lara awọn eeyan ilu naa to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ọpọlọpọ ibọn ni wọn ba lọwọ awọn janduku tọwọ ọlọpaa tẹ ọhun. Ibọn oyinbo mẹfa, ibọn ibilẹ mẹrindinlogun ati ọta ibọn bii mẹẹdogun. Wọn ni lojiji ni wahala bẹ silẹ niluu Aba Tuntun, lasiko ti awọn ọlọpaa n mura lati kuro ninu ilu naa lẹyin tọwọ ti tẹ awọn eeyan kan pẹlu ohun ija oloro lọwọ. Awọn kan ninu ilu naa ni wọn sọ pe wọn kọ lu wọn, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn, nin...

Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba

Image
Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba Posted by Sola Lawson Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba Ewo ninu won ni oba ilu tiyin Ooni of Ile-Ife Alaafin of Oyo Awujale of Ijebuland Alake of Egbaland Olowu of Owu Oluwo of Iwo Olubadan of Ibadan Soun of Ogbomoso Oba of Benin Owa Obokun of Ijesha Osemawe of Ondo Ataoja of Osogbo Deji of Akure Timi of Ede Orangun of Ila Alapa of Okin-Apa Eleko of Eko Aresa of Iresa (Aresapa of Iresa apa, Aresadu of Iresa Adu) Olugbon of Orile Igbon Onikoyi of Ikoyi Alaje of Ilu-Aje Okere of Saki Aseyin of Iseyin Onilala of Lanlate Eleruwa of Eruwa Alaketu of Ketu Alepata of Igboho Olugbo of Ugbo Olowo of Owo Ajero of Ijero-Ekiti Alara of Aramoko-Ekiti Alawe of Ilawe-Ekiti Ewi of Ado-Ekiti Ologotun of Ogotun-Ekiti Oloye of Oye-Ekiti Owa Ooye of Okemesi-Ekiti Olu of Itori Alaga of Aga-Olowo Olusi of Usi Olofa of Ofa ọwá of idanre Akarigbo of Remo Olu of Mushin Alaperu of I...

Enuduisu Odili sexual Port Harcourt death: Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji

Image
Enuduisu Odili sexual Port Harcourt death: Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji ORÍṢUN ÀWÒRÁN, NAIJA INFO Ẹbi ọkunrin ẹni ogoji ọdun, Enuduisu Odili to ku ninu ile itura, otẹẹli lẹyin to ni ajọsepọ pẹlu obinrin kan ti n bere fun iwadii to yanranti lati ọdọ ọlọpaa. Iṣẹlẹ to waye lọjọbọ ni agbegbe Mile 2, Diobu, ni Port Harcourt, ipinlẹ Rivers to wa ni Guusu-guusu Naijiriani wọn sọ pé ọkunrin kan ku lẹyin to lọ gbadun ara rẹ ni otẹẹli kan. Ko si ẹni to ye nkan ti o ṣẹlẹ ni pato ninu yara naa laarin ọkunrin to d'ologbe naa ati obinrin ọhun, sugbọn alẹ ọjọbọ naa lo gba yara naa ti wọn si ba oku rẹ ni owuro ọjọ Eti. Aburo oloogbe oun Chukwuemeka Odili salaye fun oniroyin lorukọ gbogbo ẹbi ni ejo lọwọ ninu lori ọrọ naa. Chukwuemeka ke pe kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers Joseph Mukan ati àti awọn ẹsọ alaabo to ku lati wadii nkan to fa iku ojiji ti ẹgbọn oun ku ati lati ri idajọ ododo. Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi Ẹwẹ, agbẹnus...

Alaafin Oyo: Oba Lamidi Adeyemi ní ''tí a bá yọwọ́ àwọn ọba alayé kúrò, kò ní sí Nàìjíríà mọ́

Image
Alaafin Oyo: Oba Lamidi Adeyemi ní ''tí a bá yọwọ́ àwọn ọba alayé kúrò, kò ní sí Nàìjíríà mọ́ ORÍṢUN ÀWÒRÁN, FACEBOOK/ALAAFIN OBA ADEYEMI III Awọn Yoruba maa sọ pe agba ko ni tan lorilẹ. Eyi lo difa fun ọrọ nla kan ti Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi sọ laipẹ yii laafin Oyo. Alaafin ni ti a ba yọwọ awọn ọb alaye kuro, ko ni si ohun ti a n pe ni Naijiria mọ. Alaafin sọrọ yii nigba ti Emir ilu Kano, Alhaji Aminu Ado-Bayero kan si i ni aafin rẹ niluu Oyo. ''Ni ọpọ igba ni mo ti kọ nipa iṣepataki ojuṣe awọn lọba lọba ninu idasoke orilẹede Naijiria,'' Alaafin lo sọ bẹẹ. Alaafin sọ fun Ado-Bayero pe inu oun dun pẹlu baba rẹ to ti waja nitori awọn jọ ja fita fita fun ida marun un owo to n lọ si ijọba ibilẹ tawọn ọba n jẹ anfaani rẹ lonii awọn si ṣẹgun. Oba Adeyemi ni oun yoo teṣiwaju lati maa ja fun awọn ọba alaye nitori awọn gan an ni oṣuka ti ko jẹ ki ẹru awujọ yi danu. ''Nitori naa, lai si awọn ọba alaye, ko le si ohun ti ba maa pe ni Naijiria mọ,...

ọlọpaa ṣekilọ fawọn to fẹẹ bẹrẹ iwọde SARS lẹẹkeji l’Ekoo

Image
ÌRÒYÌN   Lagos CP Hakeem Odumosu ọlọpaa ṣekilọ fawọn to fẹẹ bẹrẹ iwọde SARS lẹẹkeji l’Ekoo Sola Lawson Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, ti tun laago ikilọ setiigbọ awọn ọdọ ataraalu pe awọn o ni i faaye gba ohunkohun to jọ iwọde tabi ifẹhonu han nipinlẹ naa, bo ti wu ko kere mọ, tori naa, ki gbogbo ẹni to ba n gbero rẹ tete kuro nidii nnkan bẹẹ. Alukoro ileeṣẹ naa, SP Olumuyiwa Odumosu, lo fi ikede naa ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde yii, lorukọ ọga rẹ. Ninu alaye to ṣe, Odumosu ni awọn ti gbọ nipa bawọn eeyan kan ṣe tun bẹrẹ si i mura ija, ti wọn n gba awọn ọdọ kan jọ, ti wọn si tun fẹẹ dana iwọde ti wọn pe ni #EndSARS 2 (Iwọde ta ko SARS keji) nipinlẹ naa. O ni olobo to ta awọn fihan pe ọjọ Aje, Mọnde yii, ni wọn fẹẹ bẹrẹ kinni ọhun lawọn ikorita kan ti wọn ti yan laayo. Odumosu ni rogbodiyan ati adanu nla ti iwọde ta ko SARS to waye kọja fa fawọn olugbe ipinlẹ Eko ko ti i kuro lọkan ọpọ eeyan, otutu rẹ ṣi n mu wọn, paapaa awọn to padanu mọlẹbi wọn sinu wahala ...

Ọlọpaa ṣawari awọn ọmọde mẹwaa ti wọn loyun ni Mowe, obinrin kan lo n ta awọn ọmọ ti wọn ba bi

Image
ÌRÒYÌN Ọlọpaa ṣawari awọn ọmọde mẹwaa ti wọn loyun ni Mowe, obinrin kan lo n ta awọn ọmọ ti wọn ba bi Sola Lawson, Ipe Akoko Ile kan wa lagbegbe Ọfada si Mowe, nipinlẹ Ogun, awọn ọmọbinrin tọjọ ori wọn ko ju mejidinlogun si mẹrinlelogun lọ ni wọn n ṣabiyamọ nibẹ, ti iya kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Florence Ogbonna si n ta awọn ọmọ ti wọn ba bi, to n fowo ẹ ṣararindin. Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo jẹ ki aṣiri ohun ti wọn n ṣe ninu ile naa tu lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila, ọdun yii.  Wọn ya bo ile naa lẹyin ti olobo ta wọn, nibẹ ni wọn si ti ko awọn ọmọdebinrin mẹwaa ti wọn ṣe ikun kinrindin pẹlu oyun jade. Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bi CP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ naa sita ṣe wi ni pe iya ti wọn n pe ni Florence Ogbonna yii maa n lọọ ko awọn ọmọdebinrin ọlọmọge wa lati awọn ipinlẹ bii, Imo, Abia ati Ebonyi. Yoo sọ fawọn obi wọn labule pe iṣẹ wa l’Ekoo toun yoo fi wọn si, ko si ni i pẹ tawọn ọmọ naa yoo fi maa fowo ranṣẹ si wọn. N lawọn obi yoo ba yọnda awọn ọmọ wọn fun un. ...

Ooni Ile Ife: Emir Kano bẹ ààfin Ọọ̀ni wò, Ọọni Ogunwusi ṣàlàyé ìpayà tó gbòde lórí yíyọ tí Ganduje yọ Sanusi lóyé Emir Kano

Image
Ooni Ile Ife: Emir Kano bẹ ààfin Ọọ̀ni wò, Ọọni Ogunwusi ṣàlàyé ìpayà tó gbòde lórí yíyọ tí Ganduje yọ Sanusi lóyé Emir Kano ORÍṢUN ÀWÒRÁN, ILE OODUA Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ni ibẹru bojo gbode nigba ti ayipada ipo waye ni ilu Kano nitori gbogbo eeyan lo mọ pe bi wahala ba ṣẹlẹ ni ilu Kano, nnkan o lee rọrun lorilẹede Naijiria. Ọọni ile ifẹ ṣalaye pe nigba ti ijọba ipinlẹ Kano rọ Emir Sanusi Lamido Sanusi loye to yan Emir Ado Bayero sipo, ọkan ọpọ eeyan lo n gbọn riri nitori ko si ẹni to mọ ibi ti afẹfẹ ọrọ naa yoo fẹ si. Ọọni Adeyẹye Ogunwusi sọrọ yii lasiko ti Emir ilu Kano, Alhaji Ado Bayero bẹ ẹ wo ni aafin rẹ nilu Ile Ifẹ "Ọlọrun ṣeun fun alaafia to jọba nigba ti Emir tuntun joye ni ilu Kano. Gbogbo wa lẹru ba lori iyipo pada to waye ni Kano nitori a mọ pe wahala yoo wa ni Naijiria bi wahala ba bẹ silẹ ni ilu Kano, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe alaafia jọba." Ọọni Ogunwusi ṣalaye pe lara ohun to mu alaafia jọba lorilẹede Naijiria ni irẹpọ to wa laarin awọn ọbal...