Enuduisu Odili sexual Port Harcourt death: Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji

Enuduisu Odili sexual Port Harcourt death: Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji


Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji

Ẹbi ọkunrin ẹni ogoji ọdun, Enuduisu Odili to ku ninu ile itura, otẹẹli lẹyin to ni ajọsepọ pẹlu obinrin kan ti n bere fun iwadii to yanranti lati ọdọ ọlọpaa.

Iṣẹlẹ to waye lọjọbọ ni agbegbe Mile 2, Diobu, ni Port Harcourt, ipinlẹ Rivers to wa ni Guusu-guusu Naijiriani wọn sọ pé ọkunrin kan ku lẹyin to lọ gbadun ara rẹ ni otẹẹli kan.

Ko si ẹni to ye nkan ti o ṣẹlẹ ni pato ninu yara naa laarin ọkunrin to d'ologbe naa ati obinrin ọhun, sugbọn alẹ ọjọbọ naa lo gba yara naa ti wọn si ba oku rẹ ni owuro ọjọ Eti.

Aburo oloogbe oun Chukwuemeka Odili salaye fun oniroyin lorukọ gbogbo ẹbi ni ejo lọwọ ninu lori ọrọ naa.

Chukwuemeka ke pe kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers Joseph Mukan ati àti awọn ẹsọ alaabo to ku lati wadii nkan to fa iku ojiji ti ẹgbọn oun ku ati lati ri idajọ ododo.



Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Ẹwẹ, agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers Nnamdi Omoni naa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si fi kun pe obinrin ti o ba arakunrin naa ni ajọṣe pọ ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii

O fi kun pe wọn ti dari ẹjọ naa si ẹka iwadii iwa ọdaran ni ipinlẹ River fun iwadii to peye.

Comments

Popular posts from this blog

Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba

Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu

Lẹyin ti wọn pa ọba alaye, awọn agbebọn tun ji iyawo olori oṣiṣẹ Akeredolu lọ l’Ondo