Lẹyin ti wọn pa ọba alaye, awọn agbebọn tun ji iyawo olori oṣiṣẹ Akeredolu lọ l’Ondo
Lẹyin ti wọn pa ọba alaye, awọn agbebọn tun ji iyawo olori oṣiṣẹ Akeredolu lọ l’Ondo
Sola Lawson
Gbogbo ipa ni ijọba ipinlẹ Ondo n sa bayii lati ri i pe wọn gba iyawo Olori oṣiṣẹ lọọfiisi gomina, Ọgbẹni Olugbenga Ale, silẹ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn ji obinrin naa gbe niluu Owẹnna, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nipinlẹ Ondo.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, la gbọ pe obinrin naa pẹlu awọn kan ti wọn jọ wa ninu mọto n bọ lati ipinlẹ Eko, ti wọn si n pada lọ siluu Akurẹ.
Laarin ọna ni awọn ajinigbe naa ti da mọto ti obinrin yii wa ninu rẹ duro, niṣe ni wọn si fa a bọ silẹ ninu mọto ọhun, ti wọn si wọ ọ wọ inu igbo lọ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
A ko ti i le fidi rẹ mulẹ boya oun nikan ni wọn ji gbe ninu ọkọ naa.
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa obinrin naa, awọn ajinigbe ọhun ko si ti i pe awọn mọlẹbi lati sọ iye owo ti wọn feẹ gba.
Vanguard Yoruba gbọ pe wọn ti fọrọ naa lọ ikọ Amọtẹkun lati ran wọn lọwọ lori bi wọn ṣe le ri obinrin yii.
Bakan naa ni wọn ni Gomina Akeredolu ti ṣabewo si awọn mọlẹbi ọkunrin yii, o si fọkan wọn balẹ pe obinrin naa yoo di riri
Comments
Post a Comment