Wọn gun ẹni kan pa nibi ija awọn eegun atawọn Ibo l’Akurẹ



Wọn gun ẹni kan pa nibi ija awọn eegun atawọn Ibo l’Akurẹ

Sola Lawson, Akurẹ

Ẹni kan ni wọn lo ti pade iku ojiji lasiko tawọn ọmọ ẹyin egungun kan atawọn ọmọ Ibo to n taja lagbegbe Ọjaa’ba, niluu Akurẹ, kọju ija sira wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii.

Ẹnikan tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ sọ fun wa pe awọn oniṣowo ọhun ni wọn kọkọ gun ọkan lara awọn ọmọlẹyin egungun naa lọbẹ pa laduugbo Odopetu.

Eyi lo bi awọn ẹgbẹ rẹ ninu ti wọn fi lọọ ya bo ibi tawọn ọmọ Ibo ti n taja niwaju ileetaja Olukayọde, eyi to wa nitosi Ọjaa’ba lati gbẹsan iku ọkan ninu wọn.

Awọn janduku ọhun ni wọn n yinbọn kikan kikan, ti gbogbo eto ọrọ aje ọja agbegbe naa si dorikodo pẹlu bi olukuluku awọn ontaja ṣe fi ọja wọn silẹ, ti won si n sa asala fun ẹmi wọn.

O to bii wakati kan ti wọn fi wa lẹnu rẹ kawọn ọlọpaa too waa tu wọn ka

Comments

Popular posts from this blog

Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba

Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu

Lẹyin ti wọn pa ọba alaye, awọn agbebọn tun ji iyawo olori oṣiṣẹ Akeredolu lọ l’Ondo