Skip to main content

Alaafin Oyo: Oba Lamidi Adeyemi ní ''tí a bá yọwọ́ àwọn ọba alayé kúrò, kò ní sí Nàìjíríà mọ́

Alaafin Oyo: Oba Lamidi Adeyemi ní ''tí a bá yọwọ́ àwọn ọba alayé kúrò, kò ní sí Nàìjíríà mọ́


Alaafin ati Ooni

Awọn Yoruba maa sọ pe agba ko ni tan lorilẹ. Eyi lo difa fun ọrọ nla kan ti Alaafin Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi sọ laipẹ yii laafin Oyo.

Alaafin ni ti a ba yọwọ awọn ọb alaye kuro, ko ni si ohun ti a n pe ni Naijiria mọ.

Alaafin sọrọ yii nigba ti Emir ilu Kano, Alhaji Aminu Ado-Bayero kan si i ni aafin rẹ niluu Oyo.


''Ni ọpọ igba ni mo ti kọ nipa iṣepataki ojuṣe awọn lọba lọba ninu idasoke orilẹede Naijiria,'' Alaafin lo sọ bẹẹ.

Alaafin sọ fun Ado-Bayero pe inu oun dun pẹlu baba rẹ to ti waja nitori awọn jọ ja fita fita fun ida marun un owo to n lọ si ijọba ibilẹ tawọn ọba n jẹ anfaani rẹ lonii awọn si ṣẹgun.

Oba Adeyemi ni oun yoo teṣiwaju lati maa ja fun awọn ọba alaye nitori awọn gan an ni oṣuka ti ko jẹ ki ẹru awujọ yi danu.

''Nitori naa, lai si awọn ọba alaye, ko le si ohun ti ba maa pe ni Naijiria mọ,'' Alaafin 

Alaafin ko ṣai fi aidunnu rẹ lori eto iṣejọba ko ṣe gba ibi yan awọn ọba alaye mọ.

Ado-Bayero ati Alaafin Oyo

Ninu ọrọ tiẹ, Emir ilu kano Ado-Bayero sọ pe iyi lo jẹ fun oun lati ṣe abẹwo si Alaafin lode Oyo.

O ni oun pinnu lati kan si Alaafin fun itẹsiwaju ibaṣepọ to ti pẹ to wa laarin baba oun, Emir ilu Kano to ti waja ati Oba Adeyemi.

''A wa si ilu Oyo lati mu omi ọgbọn ati lati gba ire lọdọ Alaafin,'' Ado-Bayero lo sọ bẹẹ.

Ado-Bayero fikun ọrọ rẹ pe ilu Oyo ati kano ni ọpọ nkan ti wọn jọ ara wọn lati ẹka eto ẹkọ, aṣa to fi de ibi ọrọ okowo ati ọrọ-aje.

O ni ko si ẹni to le kọ iyan Alaafin kere ni Naijiria ninu ki eeyan mọ itan

Comments

Popular posts from this blog

Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba

Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu

Lẹyin ti wọn pa ọba alaye, awọn agbebọn tun ji iyawo olori oṣiṣẹ Akeredolu lọ l’Ondo