Olufon ti Ifon, Oba Isreal Adewusi kàgbákò ikú òjijì lọ́wọ́ àwọn afurasí ajínigbé
Olufon ti Ifon, Oba Isreal Adewusi kàgbákò ikú òjijì lọ́wọ́ àwọn afurasí ajínigbé

Iroyin kan to n lọ ni pe awọn afurasi ajinigbe ti pa ọba kan nipinlẹ Ondo, Olufon ti Ifon, Ọba Isreal Adewusi.
Ijọba ibilẹ Ose ni ilu Ifon wa, nitosi ilu Owo.
Alẹ Ọjọbọ ni iroyin naa jade sori ayelujara.
Iroyin sọ pe lasiko ti ọba naa nn pada si ilu rẹ, lẹyin ipade awọn lọba-lsba to lọ fun nilu Akure, ni awọn ajinigbe naa kọlu.
A gbọ pe ni agbegbe Elegbeka, ni awọn agbebọn naa ti jade lati inu igbo, ti wọn si yinbọn mọ ọkọ rẹ laimọye igba.
Boti lẹ jẹ pe ao ti mọ koko bi ọrọ ṣe jẹ, iroyin sọ pe awọn ajinigbe naa bẹrẹ si ni yinbọn ọkọ rẹ, lati da a duro.
Awọn miran sọ pe bi ọkọ Kabiesi ṣe n lọ, ni awọn afurasi ajinigbe naa da ọkọ duro, amọ awakọ rẹ to fura si wọn gbiyanju lati salọ. Eyi si lo mu wọn bẹrẹ si ni yinbọn mọ ọkọ naa.
Lara awọn ọta ibọn ti wọn yin lo ba Kabiesi.
Wọn gbe e de ileewosan ijọba apapọ to wa nilu Owo, nibi to ti dagbere faye.
Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́
Comments
Post a Comment