Boko Haram ṣoro, àgbẹ̀ 40 ni wọ́n pa táwọn mẹ́fà sì farapa ní Jere
Boko Haram ṣoro, àgbẹ̀ 40 ni wọ́n pa táwọn mẹ́fà sì farapa ní Jere

ORÍṢUN ÀWÒRÁN,AFP
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti bu ẹnu at lu bi awọn agbevọn kan ṣe pa agbẹ ogoji.
Aarẹ ṣapejuwe ohun ti wọn wọn ṣe yii ninu atẹjade ti agbẹnusọ aarẹ, Garba Shehu fi sita loju opo Twitter bii iwa ẹni to sinwin.
"Mo bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbesunmọmi ṣe pa awọn agbẹ wa to n ṣiṣẹ karakara lori oko irẹsi wọn ni ipinlẹ Borno.
Iṣẹlẹ dun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lapapọ bẹẹ si ni ọkan mi wa lọdọ idile awọn agbẹ yii lasiko ti wọn kẹdun awọn eeyan wọn".
Aarẹ gbadura ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.
Iroyin naa to tẹwa lọwọ lalẹ ọj Abamẹta sọ pe awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram ti ṣeku pa awọn agbẹ ogoji to n ṣiṣẹ ni oko wọn lọjọ Abamẹta kan naa.
Lowurọ ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ to fọwọ kan ni lẹmi yi waye ni agbegbe Kwashebe Zamarmari ijọba ibilẹ Jere gẹgẹ bi awọn aradugbo ṣe sọ fun kọlé fídíò,
Ọkùnrin tó fẹ́ fipábámilòpọ̀ fín ǹkan sí mi lójú ló ṣe rọ́nà wọlé sí mi lára
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, agbegbe naa jẹ ibi kan ti awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram ati ikọ Islamic State West Africa Group kii ṣe alejo pẹlu ikọlu wọn.
Amọ ko tii si ẹgbẹ kankan bii alara to jade wa sọ pe awọn lawọn ṣe ikọlu naa.
Wọn ni lasiko tawọn agbẹ naa n ge irẹsi loko ni ikọlu yi waye.
Eeyan mẹfa mi lagbọ pe wọn farapa ninu ikọlu yi.
Iroyin kan sọ pe wọn so awọn agbẹ naa mọ igi ti wọn si fi ọbẹ ge wọn lọrun.
Titi di bi a ti ṣe n sọrọ yi, ileeṣẹ ologun Naijiria ati ileeṣẹ ọlọpaa ko ti fesi si iṣẹlẹ yi.
Boko Haram ati ISWAP si n da bira lariwa orileede Naijiria toun ti pe awọn alaṣẹ ni awọn ti kapa wọn.
Loṣu to ṣẹṣẹ kọja yii ni ikọ Boko Haram pa agbẹ mejilelogun to n ṣiṣẹ loko wọn ninu iṣẹlẹ meji ọtọọtọ.
Comments
Post a Comment