Adewale Adeyemo: Wally ọmọ Yoruba tí yóò jẹ igbákejì akọ̀wé akápò ní ilẹ̀ Amẹrika
Adewale Adeyemo: Wally ọmọ Yoruba tí yóò jẹ igbákejì akọ̀wé akápò ní ilẹ̀ Amẹrika

ORÍṢUN ÀWÒRÁN,WALLY ADEYEMO/TWITTER
Agbẹjọrọ Adewale Adeyemo ni o ṣiṣẹ gẹgẹ bi olubadamọran lori eto ọrọ aje lagbaye lasiko ti aarẹ Barack Obama wa ni ipo.
Bẹẹ si ni ileeṣẹ iroyin nilẹ Amerika ni o ṣeeṣe ki o jẹ igbakeji akọwe akapo lorilẹede Amẹrika.
Adeyemo yoo ma ṣiṣẹ pọ pẹlu Arabinrin Janet Yellen ti yoo jẹ adari ẹka akapo owo lorilẹede Amẹrika labẹ iṣejọba Joe Biden.
Adeyemọ wa lara awọn eniyan jankanjankan ti awọn eniyan n reti ki aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ọhun, Joe Biden kede gẹgẹ bi awọn ti yoo ba a ṣiṣẹ ni iṣejọba rẹ.
Tani ọmọ Yoruba, Adewale Adeyemo tí yóò jẹ igbákejì akọ̀wé akápò ní ilẹ̀ Amẹrika?
Orilẹede Naijiria ni wọn ti bi Adewale Adeyemo ti wọn n pe ni ''Wally'' lọdun 1981, amọ ipinlẹ California, lorilẹede Amẹrika lo ti dagba.
Ileewe giga California lo ti gba iwe eri alakọkọ, ki o to lọ si ile ẹkọ imọ ofin ni Yale Law School.
Ki Adeyemo to ṣiṣẹ pẹlu ijọba aarẹ tẹlẹri Barack Obama, lo ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olootu iṣẹ akanṣe Hamilton, to si tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi igbakeji adari oṣiṣẹ ni ẹka akapo owo
Lẹyin eyi lo ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari iduna dunra ikọ adehunTrans-Pacific Partnership, to si tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari oṣiṣẹ ni ileeṣẹ Consumer Financial Protection Bureau, labẹ isakoso Elizabeth Warren.
Ni ọdun 2015 ni Barack Obama yan an lati ṣiṣẹ ni ipo igbakeji oludamọran lori eto abo fun ẹka idokowo lagbaye ati igbakeji adari ajo to n risi ọrọ aje lorilẹede Amerika.
O tu ti jẹ aarẹ akọkọ fun ajọ iranwọ aarẹ Barack Obama, iyẹn Obama Foundation.
Comments
Post a Comment