Posts

Yoruba Nation National Anthem....

Image
Yoruba Nation National Anthem.... Ìṣe wa fún ilé wa Fún ilé ibi wa Ká gbé ga, ká gbé ga Ká gbé ga f'aiye ri Ìgbàgbọ́ wa ni pé B'a ti b'ẹrú, là b'ọmọ K'á ṣiṣẹ́, k'á ṣiṣẹ́ K'á ṣíṣe, kajola  Iṣọ̀kan àti Ominira Ní k'ẹ jẹ́ ká máa lepa 'Tesiwaju, f' ọ̀pọ̀ ire At'oun to dára Ọmọ. Oodua dide Bọ́ s'ipo ẹtọ́ rẹ́ Ìwọ ni imọ́lẹ̀ Ògo Adúláwọ.. .C Channel YORÙBÁ News Nigeria All rights reserved. This material and any other digital content on this platform may not be reproduced, published, broadcast, written or distributed in full or in part, without written permission from SMART NEWS. BY SOLA LAWSON

Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu

Image
ÌRÒYÌN Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu   Aṣaaju apapọ fẹgbẹ oṣelu All People’s Congress, APC, to tun jẹ eekan oloṣelu Eko, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ idi toun fi kọ lati ṣatilẹyin fun Akinwunmi Ambọde nigba tọkunrin naa fẹẹ lọ fun saa keji nipo gomina ipinlẹ Eko, o ni ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ lasiko naa ki i ṣoju ọna rara, awọn o si le laju silẹ ki ilu Eko wọ’gbẹ. Tinubu ni lati bii ọdun 2017 si 2018 lo ti n han kedere pe Ambọde ti yẹsẹ lori ila to ba nilẹ to yẹ ko maa tọ, eyi to le yẹ ko mu ilu Eko de ebute ayọ to jẹ afojusun awọn aṣaaju wa. Tinubu sọrọ yii nibi ayẹyẹ ṣiṣi afara Pen-Cinema tuntun eyi to waye l’Agege, lọjọ Ẹti, Furaidee yii. Tinubu ni bawọn agba oloṣelu ilu Eko ṣe ṣakiyesi awọn aṣiṣe ti gomina ana naa ṣe lo fa a ti wọn fi gbaruku ti Babajide Sanwo-Olu ati Igbakeji ẹ, Ọbafẹmi Hamzat, fun ipo gomina, bo tilẹ jẹ pe awọn o mọ, inu oun si dun pe awọn mejeeji ko ja araalu kulẹ. O ni to ba jẹ awọn mi-...

Miliọnu meji dọla ati miliọnu mẹtadinlogun naira ni wọn ko laafin mi lasiko iwọde SARS – Ọba Akiolu

Image
Miliọnu meji dọla ati miliọnu mẹtadinlogun naira ni wọn ko laafin mi lasiko iwọde SARS – Ọba Akiolu ÌRÒYÌN Miliọnu meji dọla ati miliọnu mẹtadinlogun naira ni wọn ko laafin mi lasiko iwọde SARS – Ọba Akiolu Ọba ilu Eko, Rilwan Arẹmu Akiolu, ti ṣalaye pe miliọnu meji owo dọla ($2million) ati milọnu mẹtadinlogun naira (N17million) ni wọn ko lọ laafin oun ni Iga Iduganran, nisalẹ Eko, lasiko iwọde ta ko SARS to waye lọdun to kọja. Yatọ si towo, ọba naa lawọn janduku tun ji ọpa aṣẹ oun gbe lọ, atawọn dukia mi-in to wa ninu aafin naa. Akiolu sọrọ yii nigba to n sọrọ nibi ṣiṣi gbọngan igbalode Glover Hall Memorial, tijọba kọ si Opopona Broad, Marina, l’Ọjọbọ, Tọsidee yii. O lawọn nnkan toun padanu lasiko ti wọn ṣe akọlu si aafin oun pọ gidi, oun si fẹ ki ijọba apapọ ṣeranwọ fun ipinlẹ Eko lati ṣe atunkọ awọn nnkan ti wọn bajẹ lasiko yanpọnyanrin ọhun. “Ma a fọwọ si ohunkohun to maa mu itẹsiwaju ba ilu Eko. Mo ti parọwa si ijọba apapọ lati ran ilu Eko lọwọ latari awọn nnkan ta a padanu las...

Wọn gun ẹni kan pa nibi ija awọn eegun atawọn Ibo l’Akurẹ

Image
ÌRÒYÌN Wọn gun ẹni kan pa nibi ija awọn eegun atawọn Ibo l’Akurẹ   Sola Lawson, Akurẹ Ẹni kan ni wọn lo ti pade iku ojiji lasiko tawọn ọmọ ẹyin egungun kan atawọn ọmọ Ibo to n taja lagbegbe Ọjaa’ba, niluu Akurẹ, kọju ija sira wọn lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii. Ẹnikan tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ sọ fun wa pe awọn oniṣowo ọhun ni wọn kọkọ gun ọkan lara awọn ọmọlẹyin egungun naa lọbẹ pa laduugbo Odopetu. Eyi lo bi awọn ẹgbẹ rẹ ninu ti wọn fi lọọ ya bo ibi tawọn ọmọ Ibo ti n taja niwaju ileetaja Olukayọde, eyi to wa nitosi Ọjaa’ba lati gbẹsan iku ọkan ninu wọn. Awọn janduku ọhun ni wọn n yinbọn kikan kikan, ti gbogbo eto ọrọ aje ọja agbegbe naa si dorikodo pẹlu bi olukuluku awọn ontaja ṣe fi ọja wọn silẹ, ti won si n sa asala fun ẹmi wọn. O to bii wakati kan ti wọn fi wa lẹnu rẹ kawọn ọlọpaa too waa tu wọn ka

Wọn ji ọlọpaa gbe ni Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, wọn tun ba mọto wọn jẹ

Image
ÌRÒYÌN Wọn ji ọlọpaa gbe ni Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, wọn tun ba mọto wọn jẹ   Sola Lawson Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣi n wa ọlọpaa kan, Emmanuel Gene, ti awọn janduku kan ji gbe niluu Aba Tuntun, n’Ijẹbu-Igbo, ipinlẹ Ogun. Ṣaaju asiko yii ni baalẹ ilu naa ti kọwe ẹsun si ileeṣẹ ọlọpaa pe awọn kan ninu ilu naa ni awọn nnkan ija oloro lọwọ, eyi ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi lagbegbe naa. ALAROYE gbọ pe ọlọpaa mẹẹẹdogun atawọn ẹṣọ fijilante bii marundinlogoji lawọn ọlọpaa ko lọ sinu ilu naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii. Ọkan lara awọn eeyan ilu naa to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe ọpọlọpọ ibọn ni wọn ba lọwọ awọn janduku tọwọ ọlọpaa tẹ ọhun. Ibọn oyinbo mẹfa, ibọn ibilẹ mẹrindinlogun ati ọta ibọn bii mẹẹdogun. Wọn ni lojiji ni wahala bẹ silẹ niluu Aba Tuntun, lasiko ti awọn ọlọpaa n mura lati kuro ninu ilu naa lẹyin tọwọ ti tẹ awọn eeyan kan pẹlu ohun ija oloro lọwọ. Awọn kan ninu ilu naa ni wọn sọ pe wọn kọ lu wọn, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn, nin...

Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba

Image
Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba Posted by Sola Lawson Eyi ni Oruko oye awon oba Alade ni Ile Oodua/Yoruba #tradition #yoruba #king #oba Ewo ninu won ni oba ilu tiyin Ooni of Ile-Ife Alaafin of Oyo Awujale of Ijebuland Alake of Egbaland Olowu of Owu Oluwo of Iwo Olubadan of Ibadan Soun of Ogbomoso Oba of Benin Owa Obokun of Ijesha Osemawe of Ondo Ataoja of Osogbo Deji of Akure Timi of Ede Orangun of Ila Alapa of Okin-Apa Eleko of Eko Aresa of Iresa (Aresapa of Iresa apa, Aresadu of Iresa Adu) Olugbon of Orile Igbon Onikoyi of Ikoyi Alaje of Ilu-Aje Okere of Saki Aseyin of Iseyin Onilala of Lanlate Eleruwa of Eruwa Alaketu of Ketu Alepata of Igboho Olugbo of Ugbo Olowo of Owo Ajero of Ijero-Ekiti Alara of Aramoko-Ekiti Alawe of Ilawe-Ekiti Ewi of Ado-Ekiti Ologotun of Ogotun-Ekiti Oloye of Oye-Ekiti Owa Ooye of Okemesi-Ekiti Olu of Itori Alaga of Aga-Olowo Olusi of Usi Olofa of Ofa ọwá of idanre Akarigbo of Remo Olu of Mushin Alaperu of I...

Enuduisu Odili sexual Port Harcourt death: Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji

Image
Enuduisu Odili sexual Port Harcourt death: Ọkùnrin kan gba ibi ìbálòpọ̀ jásí ọ̀run alákeji ORÍṢUN ÀWÒRÁN, NAIJA INFO Ẹbi ọkunrin ẹni ogoji ọdun, Enuduisu Odili to ku ninu ile itura, otẹẹli lẹyin to ni ajọsepọ pẹlu obinrin kan ti n bere fun iwadii to yanranti lati ọdọ ọlọpaa. Iṣẹlẹ to waye lọjọbọ ni agbegbe Mile 2, Diobu, ni Port Harcourt, ipinlẹ Rivers to wa ni Guusu-guusu Naijiriani wọn sọ pé ọkunrin kan ku lẹyin to lọ gbadun ara rẹ ni otẹẹli kan. Ko si ẹni to ye nkan ti o ṣẹlẹ ni pato ninu yara naa laarin ọkunrin to d'ologbe naa ati obinrin ọhun, sugbọn alẹ ọjọbọ naa lo gba yara naa ti wọn si ba oku rẹ ni owuro ọjọ Eti. Aburo oloogbe oun Chukwuemeka Odili salaye fun oniroyin lorukọ gbogbo ẹbi ni ejo lọwọ ninu lori ọrọ naa. Chukwuemeka ke pe kọmisọna ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers Joseph Mukan ati àti awọn ẹsọ alaabo to ku lati wadii nkan to fa iku ojiji ti ẹgbọn oun ku ati lati ri idajọ ododo. Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi Ẹwẹ, agbẹnus...