Posts

Showing posts from March, 2021

Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu

Image
ÌRÒYÌN Ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ ko dara la ko ṣe ṣatilẹyin fun saa keji rẹ – Tinubu   Aṣaaju apapọ fẹgbẹ oṣelu All People’s Congress, APC, to tun jẹ eekan oloṣelu Eko, Oloye Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ idi toun fi kọ lati ṣatilẹyin fun Akinwunmi Ambọde nigba tọkunrin naa fẹẹ lọ fun saa keji nipo gomina ipinlẹ Eko, o ni ibi ti Ambọde n tukọ ipinlẹ Eko lọ lasiko naa ki i ṣoju ọna rara, awọn o si le laju silẹ ki ilu Eko wọ’gbẹ. Tinubu ni lati bii ọdun 2017 si 2018 lo ti n han kedere pe Ambọde ti yẹsẹ lori ila to ba nilẹ to yẹ ko maa tọ, eyi to le yẹ ko mu ilu Eko de ebute ayọ to jẹ afojusun awọn aṣaaju wa. Tinubu sọrọ yii nibi ayẹyẹ ṣiṣi afara Pen-Cinema tuntun eyi to waye l’Agege, lọjọ Ẹti, Furaidee yii. Tinubu ni bawọn agba oloṣelu ilu Eko ṣe ṣakiyesi awọn aṣiṣe ti gomina ana naa ṣe lo fa a ti wọn fi gbaruku ti Babajide Sanwo-Olu ati Igbakeji ẹ, Ọbafẹmi Hamzat, fun ipo gomina, bo tilẹ jẹ pe awọn o mọ, inu oun si dun pe awọn mejeeji ko ja araalu kulẹ. O ni to ba jẹ awọn mi-...

Miliọnu meji dọla ati miliọnu mẹtadinlogun naira ni wọn ko laafin mi lasiko iwọde SARS – Ọba Akiolu

Image
Miliọnu meji dọla ati miliọnu mẹtadinlogun naira ni wọn ko laafin mi lasiko iwọde SARS – Ọba Akiolu ÌRÒYÌN Miliọnu meji dọla ati miliọnu mẹtadinlogun naira ni wọn ko laafin mi lasiko iwọde SARS – Ọba Akiolu Ọba ilu Eko, Rilwan Arẹmu Akiolu, ti ṣalaye pe miliọnu meji owo dọla ($2million) ati milọnu mẹtadinlogun naira (N17million) ni wọn ko lọ laafin oun ni Iga Iduganran, nisalẹ Eko, lasiko iwọde ta ko SARS to waye lọdun to kọja. Yatọ si towo, ọba naa lawọn janduku tun ji ọpa aṣẹ oun gbe lọ, atawọn dukia mi-in to wa ninu aafin naa. Akiolu sọrọ yii nigba to n sọrọ nibi ṣiṣi gbọngan igbalode Glover Hall Memorial, tijọba kọ si Opopona Broad, Marina, l’Ọjọbọ, Tọsidee yii. O lawọn nnkan toun padanu lasiko ti wọn ṣe akọlu si aafin oun pọ gidi, oun si fẹ ki ijọba apapọ ṣeranwọ fun ipinlẹ Eko lati ṣe atunkọ awọn nnkan ti wọn bajẹ lasiko yanpọnyanrin ọhun. “Ma a fọwọ si ohunkohun to maa mu itẹsiwaju ba ilu Eko. Mo ti parọwa si ijọba apapọ lati ran ilu Eko lọwọ latari awọn nnkan ta a padanu las...